ORIKI KABIYESI

Ojukere Odulana isola B’okan ba ju’kan
Omo Olanrewaju Oba nii ko won roro
Isola Okin Omo Odugade Oba o k’eyin mo, t’e yin diran
Ojukere ambese Olalomi, omo abisu jooko
Ise ameleja j’ekun Ijakadi loro Ofa
Imoran agbonrin ti nda’ Ijakan, ijakan ti won nja l’Ofa
Ko je’kun loju N’ile Olalomi, o s’oju taa ni?
E je ki oloungini o da tie O s’oju laporubu ka’ko
‘Ka woran O s’oju a gun mona l’ebe
Oka oju ona tii le furukoko s’olode O s’oju a gbe’le ya’ rara
Iyeru okin Abilofa Isu ni l’aporuku ka’ko
Arinlolu Eree l’agbe ‘le ya’ rara
Olalomi omo abisu joo ko Isu ni la’poruku ka’ko
Ijakadi loro Ofa Eree l’agbe ‘le ya‘rara
Ija peki a be owula Isu ni l’aporuku ka’ko
Ija o po tan e ma e lo mi Agbado ta’gun m’ona mo te l’ebe
Olalomi omo a di’ju kaa to la isu Oka-a-baba ni l’agun a k’orun
Okan o gbodo ju’kan Olalomi omo a b’isu joo ko.